Isikiẹli 1:22-28 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Kinní kan bí awọsanma tí ó ń dán bíi Kristali wà lórí àwọn ẹ̀dá alààyè náà, ó tàn bo gbogbo orí wọn.

23. Lábẹ́ kinní bí awọsanma yìí ni àwọn ìyẹ́ wọn ti nà jáde, wọ́n kan ara wọn, àwọn ẹ̀dá alààyè náà ní ìyẹ́ meji meji tí wọ́n fi bora.

24. Bí wọ́n ti ń lọ, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn, ó dàbí ariwo odò ńlá, bí ààrá Olodumare, bí ariwo ìdágìrì ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Bí wọ́n bá dúró, wọn a ká ìyẹ́ wọn wálẹ̀,

25. nǹkankan a sì máa dún lókè awọsanma tí ó wà lórí wọn. Bí wọn bá ti dúró, wọn a ká ìyẹ́ wọn wálẹ̀.

26. Mo rí kinní kan lókè awọsanma tí ó wà lórí wọn, ó dàbí ìtẹ́ tí a fi òkúta safire ṣe; mo sì rí kinní kan tí ó dàbí eniyan, ó jókòó lórí nǹkankan bí ìtẹ́ náà.

27. Mo wò ó láti ibi tí ó dàbí ìbàdí rẹ̀ lọ sókè, ó rí bíi bàbà dídán, ó dàbí iná yíká. Mo wò ó láti ibi ìbàdí lọ sí ìsàlẹ̀, ó dàbí iná. Ìmọ́lẹ̀ sì wà ní gbogbo àyíká rẹ̀.

28. Ìmọ́lẹ̀ tí ó yí i ká dàbí òṣùmàrè tí ó yọ ninu ìkùukùu lákòókò òjò. Bẹ́ẹ̀ ni àfiwé ìfarahàn ògo OLUWA rí. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo bá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ń sọ̀rọ̀.

Isikiẹli 1