Ìfihàn 5:12-14 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Wọ́n ń kígbe pé,“Ọ̀dọ́ Aguntan tí a ti pa ni ó tọ́ síláti gba agbára, ọrọ̀, ọgbọ́n, ipá, ọlá, ògo ati ìyìn.”

13. Mo bá tún gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tí ó wà lọ́run ati ní orílẹ̀ ayé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀, ati lórí òkun, ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu òkun, ń wí pé,“Ìyìn, ọlá, ògo, ati agbára ni ti ẹnití ó jókòó lórí ìtẹ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan lae ati laelae.”

14. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá dáhùn pé, “Amin!” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun.

Ìfihàn 5