24. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa rìn ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn ọba ilé-ayé yóo mú ọlá wọn wá sinu rẹ̀.
25. Wọn kò ní ti àwọn ìlẹ̀kùn ìlú náà ní gbogbo ọ̀sán; òru kò sì ní sí níbẹ̀.
26. Wọn yóo mú ẹwà ati ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sí inú rẹ̀.
27. Ohun ìdọ̀tí kan kò ní wọ inú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá ń ṣe ohun ẹ̀gbin tabi èké kò ní wọ ibẹ̀. Àwọn tí a ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Aguntan nìkan ni yóo wọ ibẹ̀.