Ìfihàn 21:2-12 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Lẹ́yìn náà mo rí ìlú mímọ́ náà, Jerusalẹmu titun, tí ó ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sọ̀kalẹ̀ láti òkè wá. A ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ bí ìgbà tí a bá ṣe iyawo lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀.

3. Mo wá gbọ́ ohùn líle kan láti orí ìtẹ́ náà wá tí ó wí pé, “Ọlọrun pàgọ́ sí ààrin àwọn eniyan, yóo máa bá wọn gbé, wọn yóo jẹ́ eniyan rẹ̀, Ọlọrun pàápàá yóo wà pẹlu wọn;

4. yóo nu gbogbo omijé nù ní ojú wọn. Kò ní sí ikú mọ́, tabi ọ̀fọ̀ tabi ẹkún tabi ìrora. Nítorí àwọn ohun ti àtijọ́ ti kọjá lọ.”

5. Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà sọ pé, “Mò ń sọ ohun gbogbo di titun.” Ó ní, “Kọ ọ́ sílẹ̀, nítorí òdodo ọ̀rọ̀ ati òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí.”

6. Ó ní, “Ó parí! Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin. N óo fún ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ ní omi mu láti inú kànga omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.

7. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni yóo jogún nǹkan wọnyi. N óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ̀, òun náà yóo sì máa jẹ́ ọmọ mi.

8. Ṣugbọn àwọn ojo, àwọn alaigbagbọ, àwọn ẹlẹ́gbin, àwọn apànìyàn, àwọn àgbèrè, àwọn oṣó, àwọn abọ̀rìṣà, ati gbogbo àwọn èké ni yóo ní ìpín wọn ninu adágún iná tí ń jó, tí a fi imí-ọjọ́ dá. Èyí ni ikú keji.”

9. Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí ó mú àwo meje lọ́wọ́, tí ìparun ìkẹyìn meje wà ninu wọn, ó wá bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní “Wá, n óo fi iyawo Ọ̀dọ́ Aguntan hàn ọ́.”

10. Ó bá gbé mi ninu ẹ̀mí lọ sí orí òkè ńlá kan tí ó ga, ó fi Jerusalẹmu ìlú mímọ́ náà hàn mí, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

11. Ògo Ọlọrun ń tàn lára rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye. Ẹwà rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye tí ó mọ́lẹ̀ gaara.

12. Odi ìlú náà nípọn, ó sì ga. Ó ní ìlẹ̀kùn mejila, àwọn angẹli mejila wà níbi àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà. A kọ àwọn orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli mejila sí ara àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà.

Ìfihàn 21