1. “Kọ ìwé yìí sí òjíṣẹ́ ìjọ Efesu:“Ẹni tí ó di ìràwọ̀ meje mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, tí ó ń rìn láàrin àwọn ọ̀pá fìtílà wúrà meje wí báyìí pé,
2. Mo mọ iṣẹ́ rẹ, ati làálàá rẹ, ati ìfaradà rẹ. Mo mọ̀ pé o kò jẹ́ gba àwọn eniyan burúkú mọ́ra. O ti dán àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọn kì í ṣe aposteli wò, o ti rí i pé òpùrọ́ ni wọ́n.
3. O ní ìfaradà. O ti farada ìyà nítorí orúkọ mi, o kò sì jẹ́ kí àárẹ̀ mú ọ.
4. Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O ti kọ ìfẹ́ tí o ní nígbà tí o kọ́kọ́ gbàgbọ́ sílẹ̀.
5. Nítorí náà, ranti bí o ti ga tó tẹ́lẹ̀ kí o tó ṣubú; ronupiwada, kí o sì ṣiṣẹ́ bíi ti àkọ́kọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, bí o kò bá ronupiwada, n óo mú ọ̀pá fìtílà rẹ kúrò ní ipò rẹ̀.
6. Ṣugbọn ò ń ṣe kinní kan tí ó dára: o kórìíra iṣẹ́ àwọn Nikolaiti, tí èmi náà kórìíra.
26-28. Ẹni tí ó bá ṣẹgun, tí ó forí tì í, tí ó ń ṣe iṣẹ́ mi títí dé òpin, òun ni n óo fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, ọ̀pá irin ni yóo fi jọba lórí wọn, bí ìkòkò amọ̀ ni yóo fọ́ wọn túútúú. Irú àṣẹ tí mo gbà lọ́dọ̀ Baba mi ni n óo fún un. N óo tún fún un ní ìràwọ̀ òwúrọ̀.