12. Wúrà, fadaka, òkúta iyebíye, oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀, aṣọ funfun ati àlàárì, ati sányán ati aṣọ pupa; oríṣìíríṣìí pákó, ati àwọn ohun èèlò tí a fi eyín erin, igi iyebíye, idẹ, irin, ati òkúta ṣe;
13. oríṣìíríṣìí òróró ìkunra, turari ati òjíá, ọtí, òróró olifi, ọkà, ati àgbàdo, ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun, ẹrú, àní ẹ̀mí eniyan.
14. Wọ́n ní, “Èso tí o fẹ́ràn kò sí mọ́, gbogbo ìgbé-ayé fàájì ati ti ìdẹ̀ra ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ, o kò tún ní rí irú rẹ̀ mọ́.”
15. Àwọn oníṣòwò wọnyi, tí wọ́n ti di olówó ninu rẹ̀ yóo dúró ní òkèèrè nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀, wọn óo máa sunkún, wọn óo máa ṣọ̀fọ̀.
16. Wọn óo máa wí pé, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà! Ìlú tí ó wọ aṣọ funfun, ati aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa. Ìlú tí wúrà pọ̀ níbẹ̀ ati òkúta iyebíye ati ìlẹ̀kẹ̀!