1. Lẹ́yìn èyí mo tún rí angẹli tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ní àṣẹ ńlá. Gbogbo ayé mọ́lẹ̀ nítorí ẹwà ògo rẹ̀.
2. Ó wá kígbe pé, “Ó tú! Babiloni ìlú ńlá tú! Ó wá di ibi tí àwọn àǹjọ̀nnú ń gbé, tí ẹ̀mí Èṣù oríṣìíríṣìí ń pààrà, tí oríṣìíríṣìí ẹyẹkẹ́yẹ ń kiri.
3. Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti mu àmuyó ninu ọtí àgbèrè rẹ̀, ọtí tí ó fa ibinu Ọlọrun. Àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn oníṣòwò ilẹ̀ ayé ti di olówó nípa ìwà jayéjayé rẹ̀.”
4. Mo tún gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run tí ó sọ pé,“Ẹ jáde kúrò ninu rẹ̀, ẹ̀yin eniyan mi,kí ẹ má baà ní ìpín ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,kí ẹ má baà fara gbá ninu ìjìyà rẹ̀.
5. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga dé ọ̀run,Ọlọrun kò gbàgbé àìṣedéédé rẹ̀.
6. Ṣe fún un bí òun náà ti ṣe fún eniyan.Gbẹ̀san lára rẹ̀ ní ìlọ́po meji ìwà rẹ̀.Ife tí ó fi ń bu ọtí fún eniyan nikí o fi bu ọtí tí ó le ní ìlọ́po meji fún òun alára.
7. Bí ó ti ṣe ń jẹ ọlá,tí ó ń jẹ ayé tẹ́lẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kí o fún un ní ìrora ati ìbànújẹ́.Ó ń sọ ní ọkàn rẹ̀ pé,‘Ọba orí ìtẹ́ ni mí,èmi kì í ṣe opó,ojú mi kò ní rí ìbànújẹ́.’