17. Angẹli keje da ohun tí ó wà ninu àwo rẹ̀ sinu afẹ́fẹ́. Ẹnìkan bá fi ohùn líle sọ̀rọ̀ láti ibi ìtẹ́ tí ó wà ninu Tẹmpili, ó ní, “Ó ti parí!”
18. Ni mànàmáná bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ, ààrá ń sán, ilẹ̀ ń mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí irú rẹ̀ rí láti ìgbà tí eniyan ti dé orí ilẹ̀ ayé.
19. Ìlú ńlá náà bá pín sí mẹta. Gbogbo ìlú àwọn orílẹ̀-èdè bá tú. Babiloni ìlú ńlá náà kò bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọrun, Ọlọrun jẹ́ kí ó mu ninu ìkorò ibinu rẹ̀.