1. Mo tún rí ohun abàmì mìíràn ní ọ̀run, ohun ńlá ati ohun ìyanu: àwọn angẹli meje tí àjàkálẹ̀ àrùn meje ti ìkẹyìn wà ní ìkáwọ́ wọn, nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibinu Ọlọrun wá sí òpin.
2. Mo tún rí ohun tí ó dàbí òkun dígí tí iná wà ninu rẹ̀. Àwọn kan dúró lẹ́bàá òkun dígí náà, àwọn tí wọ́n ti ṣẹgun ẹranko náà ati ère rẹ̀, ati iye orúkọ rẹ̀. Wọ́n mú hapu Ọlọrun lọ́wọ́,
3. wọ́n ń kọ orin Mose iranṣẹ Ọlọrun ati orin Ọ̀dọ́ Aguntan náà pé,“Iṣẹ́ ńlá ati iṣẹ́ ìyanu ni iṣẹ́ rẹ,Oluwa, Ọlọrun Olodumare.Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ,Ọba àwọn orílẹ̀-èdè.
4. Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, Oluwa?Ta ni kò ní fi ògo fún orúkọ rẹ?Nítorí ìwọ nìkan ni ó pé,nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá,wọn yóo júbà níwájú rẹ,nítorí òdodo rẹ farahàn gbangba.”