17. Angẹli mìíràn tún jáde wá láti inú Tẹmpili ní ọ̀run, tí òun náà tún mú dòjé mímú lọ́wọ́.
18. Angẹli mìíràn wá ti ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ìrúbọ wá, òun ni ó ní àṣẹ lórí iná. Ó kígbe sí angẹli tí ó ní dòjé mímú pé, “Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún dòjé mímú rẹ. Kó èso àwọn igi eléso ilé ayé jọ, nítorí pé wọ́n ti pọ́n.”
19. Ni angẹli tí ó ní dòjé náà bá ti dòjé rẹ̀ bọ inú ilé ayé, ó bá kó èso àjàrà ayé jọ, ó dà wọ́n sí ibi ìfúntí ibinu ńlá Ọlọrun.
20. Lẹ́yìn odi ìlú ni ìfúntí náà wà. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ èso ninu rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí yọ jáde láti inú ìfúntí náà. Jíjìn rẹ̀ mu ẹṣin dé ọrùn, ó sì gba ilẹ̀ lọ ní nǹkan bí igba ibùsọ̀.