2. Ó mú ìwé kékeré kan lọ́wọ́ tí ó wà ní ṣíṣí. Ó gbé ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ lé orí òkun, ó sì gbé ti òsì lé orí ilẹ̀ ayé.
3. Ó wá bú ramúramù bíi kinniun. Nígbà tí ó bú báyìí tán, ààrá meje sán.
4. Nígbà tí ààrá meje yìí ń sán, mo fẹ́ máa kọ ohun tí wọn ń sọ sílẹ̀, ṣugbọn mo gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run, tí ó sọ pé, “Àṣírí ni ohun tí àwọn ààrá meje yìí ń sọ, má kọ wọ́n sílẹ̀.”
5. Angẹli náà tí mo rí, tí ó gbé ẹsẹ̀ lé orí òkun, ati orí ilẹ̀, wá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sí òkè ọ̀run,