Wọ́n bá fà á sinu ọkọ̀ ńlá, wọ́n wá fi okùn so ó mọ́ ara ọkọ̀ ńlá. Ẹ̀rù ń bà wọ́n kí wọn má forí ọkọ̀ sọ ilẹ̀ iyanrìn ní Sitisi, wọ́n bá ta aṣọ-ọkọ̀, kí atẹ́gùn lè máa gbé ọkọ̀ náà lọ.