26. “Gomina ọlọ́lá jùlọ, Fẹliksi, èmi Kilaudiu Lisia ki yín.
27. Àwọn Juu mú ọkunrin yìí, wọ́n fẹ́ pa á. Mo gbà á lọ́wọ́ wọn pẹlu àwọn ọmọ-ogun mi nítorí mo gbọ́ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni.
28. Mo fẹ́ mọ ìdí tí wọ́n ṣe fi ẹ̀sùn kàn án. Mo bá mú un lọ sí iwájú ìgbìmọ̀ wọn.
29. Mo rí i pé ẹ̀sùn tí wọ́n ní jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ òfin wọn; kò ṣe ohunkohun tí a lè fi sọ pé kí á pa á tabi kí á jù ú sí ẹ̀wọ̀n.
30. Nígbà tí ìròyìn kàn mí pé àwọn kan láàrin àwọn Juu ti dìtẹ̀ sí ọkunrin yìí, mo bá fi í ranṣẹ si yín. Mo ti sọ fún àwọn tí ó fi ẹ̀sùn kàn án pé kí wọ́n wá sọ ohun tí wọ́n ní sí i níwájú yín.”