Ìṣe Àwọn Aposteli 23:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Paulu kọjú sí àwọn ìgbìmọ̀, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ní gbogbo ìgbé-ayé mi, ọkàn mí mọ́ níwájú Ọlọrun títí di òní.”

2. Bí ó ti sọ báyìí, bẹ́ẹ̀ ni Anania Olórí Alufaa sọ fún àwọn tí ó dúró ti Paulu pé kí wọ́n gbá a lẹ́nu.

3. Paulu wá sọ fún un pé, “Ọlọrun yóo lù ọ́. Ìwọ ògiri tí wọ́n kùn lẹ́fun lásán yìí! O jókòó sibẹ, ò ń dá mi lẹ́jọ́ lórí Òfin, sibẹ o pa Òfin tì, o ní kí wọ́n lù mí.”

Ìṣe Àwọn Aposteli 23