21. Ṣugbọn Oluwa sọ fún mi pé, ‘Bọ́ sọ́nà, nítorí n óo rán ọ lọ sí ọ̀nà jíjìn, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Juu.’ ”
22. Àwọn eniyan fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí gbolohun yìí fi jáde. Nígbà tí wọ́n gbọ́ gbolohun yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Ẹ pa irú ẹni bẹ́ẹ̀ rẹ́ kúrò láyé! Kò yẹ kí ó wà láàyè!”
23. Wọ́n bá ń pariwo, wọ́n ń fi aṣọ wọn, wọ́n sì ń da ìyẹ̀pẹ̀ sókè.
24. Ni ọ̀gágun bá pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu wọ àgọ́ ọmọ-ogun lọ. Ó ní kí wọn nà án kí wọn fi wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀, kí ó lè mọ ìdí tí àwọn eniyan ṣe ń pariwo lé e lórí bẹ́ẹ̀.
25. Bí wọ́n ti ń dè é mọ́lẹ̀ láti máa nà án, Paulu bi balogun ọ̀rún tí ó dúró pé, “Ẹ̀tọ́ wo ni ẹ níláti na ọmọ-ìbílẹ̀ Romu láì tíì dá a lẹ́jọ́?”
26. Nígbà tí balogun ọ̀rún gbọ́, ó lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun, ó bi í pé, “Kí lẹ fẹ́ ṣe? Ọmọ ìbílẹ̀ Romu ni ọkunrin yìí o!”
27. Ní ọ̀gágun bá lọ bi Paulu, ó ní, “Wí kí n gbọ́, ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni ọ́?”Paulu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”
28. Ọ̀gágun náà bá dá a lóhùn pé, “Ọpọlọpọ owó ni mo ná kí n tó di ọmọ-ìbílẹ̀ Romu.”Ṣugbọn Paulu ní, “Ní tèmi o, wọ́n bí mi bẹ́ẹ̀ ni.”
29. Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ bá bìlà. Ẹ̀rù wá ba ọ̀gágun náà nígbà tí ó mọ̀ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni Paulu, àtipé òun ti fi ẹ̀wọ̀n dè é.