1. Lẹ́yìn èyí, Paulu kúrò ní Atẹni, ó lọ sí Kọrinti.
2. Ó rí Juu kan níbẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akuila, ará Pọntu. Òun ati Pirisila iyawo rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Itali dé ni, nítorí ọba Kilaudiu pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Juu kúrò ní ìlú Romu. Paulu bá lọ sọ́dọ̀ wọn.
3. Nítorí pé iṣẹ́ kan náà ni wọ́n ń ṣe, Paulu lọ wọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó sì ń ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ ọnà awọ tí wọ́n fi ń ṣe àgọ́ ni wọ́n ń ṣe.
4. Ní gbogbo Ọjọ́ Ìsinmi, a máa bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀; ó fẹ́ yí àwọn Juu ati Giriki lọ́kàn pada.