Ni Peteru bá pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò.Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó dìde, ó bá wọn lọ. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ìjọ ní Jọpa sì tẹ̀lé wọn.