9. Ṣugbọn a rí Jesu, tí Ọlọrun fi sí ipò tí ó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju ti àwọn angẹli fún àkókò díẹ̀. Òun ni ó jẹ oró ikú, tí Ọlọrun tún wá fi ògo ati ọlá dé e ládé. Nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ó kú fún gbogbo eniyan.
10. Nítorí pé kí Ọlọrun tí ó dá gbogbo nǹkan, tí ó sì mú kí gbogbo nǹkan wà, lè mú ọpọlọpọ wá sí inú ògo, ó tọ́ kí ó ṣe aṣaaju tí yóo la ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún wọn nípa ìyà jíjẹ.
11. Nítorí ọ̀kan ni ẹni tí ó ń ya eniyan sí mímọ́ ati àwọn eniyan tí ó ń yà sí mímọ́ jẹ́, nítorí náà ni Jesu kò fi tijú láti pè wọ́n ní arakunrin rẹ̀.
12. Ó ní,“Èmi óo pe orúkọ rẹ ní gbangba fún àwọn arakunrin mi.Ní ààrin àwùjọ ni n óo yìn ọ́.”
13. Ó tún sọ pé,“Èmi ní tèmi, èmi óo gbẹ́kẹ̀lé e.”Ati pé,“Èmi nìyí ati àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi fún mi.”
14. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ jẹ́ ẹlẹ́ran-ara ati ẹlẹ́jẹ̀, Jesu pàápàá di ẹlẹ́ran-ara ati ẹlẹ́jẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wọn, kí ó lè ti ipasẹ̀ ikú rẹ̀ sọ agbára Satani tí ó ní ikú ní ìkáwọ́ di asán.
15. Ó wá dá àwọn tí ẹ̀rù ikú ti sọ di ẹrú ninu gbogbo ìgbé-ayé wọn sílẹ̀.
16. Nítorí ó dájú pé, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó wá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún bíkòṣe àwọn ọmọ Abrahamu.
17. Nítorí náà, dandan ni kí òun alára jọ àwọn arakunrin rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, kí ó lè jẹ́ Olórí Alufaa tí ó láàánú, tí ó sì ṣe é gbójú lé nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ níwájú Ọlọrun fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan.