Heberu 10:9-20 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Lẹ́yìn náà ó wá sọ pé, “Èmi nìyí, mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.” Èyí ni pé ó mú ti àkọ́kọ́ kúrò kí ó lè fi ekeji lélẹ̀.

10. Nípa ìfẹ́ Ọlọrun náà ni a fi yà wá sọ́tọ̀ nítorí ẹbọ tí Jesu fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.

11. Àwọn alufaa a máa dúró lojoojumọ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, láti máa rú ẹbọ kan náà tí kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ nígbàkúùgbà.

12. Ṣugbọn òun ṣe ìrúbọ lẹ́ẹ̀kan fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tó fún gbogbo ìgbà, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.

13. Níbẹ̀ ni ó wà tí ó ń retí ìgbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo di àpótí-ìtìsẹ̀ rẹ̀.

14. Nítorí nípa ẹbọ kan ó sọ àwọn tí a yà sọ́tọ̀ di pípé títí lae.

15. Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà fún wa. Ó kọ́kọ́ sọ báyìí pé,

16. “Èyí ni majẹmu tí n óo bá wọn dánígbà tí ó bá yá, Èmi Oluwa ni mo sọ bẹ́ẹ̀,Èmi óo fi òfin mi sí ọkàn wọn,n óo kọ wọ́n sí àyà wọn.”

17. Ó tún ní, “N kò ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú wọn mọ́.”

18. Nígbà tí a bá ti dárí àwọn nǹkan wọnyi ji eniyan, kò tún sí ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

19. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, a ní ìgboyà láti wọ Ibi Mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ ìkélé nípa ẹ̀jẹ̀ Jesu,

20. nípa ọ̀nà titun ati ọ̀nà ààyè tí ó ti yà sọ́tọ̀ fún wa tíí ṣe ẹran-ara rẹ̀.

Heberu 10