Habakuku 2:9-17 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ipá kó èrè burúkú jọ tí ẹ óo fi kọ́ ibùgbé sí ibi gíga, kí nǹkan burúkú kankan má baà ṣẹlẹ̀ si yín!

10. O ti kó ìtìjú bá ilé rẹ nítorí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè tí o parun; ìwọ náà ti wá pàdánù ẹ̀mí rẹ.

11. Nítorí òkúta yóo kígbe lára ògiri, igi ìdábùú òpó ilé yóo sì fọhùn pẹlu.

12. Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ìwà ìpànìyàn kó ìlú jọ, tí ẹ fi ìwà ọ̀daràn tẹ ìlú dó.

13. Wò ó, ṣebí ìkáwọ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó wà, pé kí orílẹ̀-èdè kan ṣe làálàá tán, kí iná sì jó gbogbo rẹ̀ ní àjórun, kí wahala orílẹ̀-èdè náà sì já sí asán.

14. Nítorí ayé yóo kún fún ìmọ̀ ògo OLUWA, gẹ́gẹ́ bí omi ti kún inú òkun.

15. Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ fi ibinu fún aládùúgbò yín ní ọtí mu, tí ẹ jẹ́ kí inú wọn ru, kí ẹ lè rí ìhòòhò wọn.

16. Ìtìjú ni yóo bò yín dípò ògo. Ẹ máa mu àmupara kí ẹ sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, ife ìjẹníyà tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún OLUWA yóo kàn yín, ìtìjú yóo sì bo ògo yín.

17. Ibi tí ó dé bá Lẹbanoni yóo bò yín mọ́lẹ̀; ìparun àwọn ẹranko yóo dẹ́rùbà yín, nítorí ìpànìyàn ati ibi tí ẹ ṣe sí ayé, sí àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn.

Habakuku 2