6. Wò ó! N óo gbé àwọn ará Kalidea dìde, orílẹ̀-èdè tí ó yára, tí kò sì ní àánú; àwọn tí wọ́n la ìbú ayé já, tí wọn ń gba ilẹ̀ onílẹ̀ káàkiri.
7. Ìrísí wọn bani lẹ́rù; wọ́n ń fi ọlá ńlá wọn ṣe ìdájọ́ bí ó ti wù wọ́n.
8. “Àwọn ẹṣin wọn yára ju àmọ̀tẹ́kùn lọ, wọ́n burú ju ìkookò tí ebi ń pa ní àṣáálẹ́ lọ. Pẹlu ìgbéraga ni àwọn ẹlẹ́ṣin wọn máa ń gun ẹṣin wọn lọ. Dájúdájú, ọ̀nà jíjìn ni àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ti ń wá; wọn a fò, bí idì tí ń sáré sí oúnjẹ.
9. “Tìjàtìjà ni gbogbo wọn máa ń rìn, ìpayà á bá gbogbo eniyan bí wọ́n bá ti ń súnmọ́ tòsí. Wọn a kó eniyan ní ìgbèkùn, bí ẹni kó yanrìn nílẹ̀.