Habakuku 1:14-17 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nítorí o ti jẹ́ kí ọmọ eniyan dàbí ẹja inú òkun, ati bí àwọn kòkòrò tí wọn ń rìn nílẹ̀, tí wọn kò ní olórí.

15. Ọ̀tá fi ìwọ̀ fa gbogbo wọn sókè, ó sì fi àwọ̀n rẹ̀ kó wọn jáde. Ó kó wọn papọ̀ sinu àwọ̀n rẹ̀, Nítorí náà ó ń yọ̀, inú rẹ̀ sì dùn.

16. Nítorí náà a máa bọ àwọ̀n rẹ̀. A sì máa fi turari rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀ ńlá; nítorí a máa rò lọ́kàn rẹ̀ pé, àwọ̀n òun ni ó ń jẹ́ kí òun gbádùn ayé tí òun sì fi ń rí oúnjẹ aládùn jẹ.

17. Ṣé gbogbo ìgbà ni àwọn eniyan yóo máa bọ́ sinu àwọ̀n rẹ̀ ni? Ṣé títí lae ni yóo sì máa pa àwọn orílẹ̀-èdè run láìláàánú?

Habakuku 1