15. kí ẹ lè jẹ́ Ọmọ Ọlọrun, tí kò lẹ́bi tí kò sì ní àléébù, ọmọ Ọlọrun tí ó pé, láàrin àwọn ìran tí ọ̀nà wọn wọ́, tí ìwà wọn sì ti bàjẹ́. Láàrin irú àwọn eniyan wọnyi ni ẹ̀ ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ ninu ayé,
16. tí ẹ sì ń polongo ọ̀rọ̀ ìyè. Èyí ni yóo jẹ́ ìṣògo fún mi ní ọjọ́ tí Kristi bá dé, nítorí yóo hàn pé iré-ìje tí mò ń sá kì í ṣe lásán, ati pé aápọn tí mo ti ṣe kò já sí òfo.
17. Ṣugbọn bí a bá fi mí ṣe ohun ìrúbọ ati ohun èèlò ninu ìsìn nítorí igbagbọ yín, ó dùn mọ́ mi, n óo sì máa yọ̀ pẹlu gbogbo yín.
18. Nítorí náà, kí inú yín kí ó máa dùn, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀.
19. Lágbára Oluwa, mò ń gbèrò ati rán Timoti si yín láì pẹ́, kí n lè ní ìwúrí nígbà tí mo bá gbúròó yín.
20. N kò ní ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀ tí ọkàn wa rí bákan náà, tí ó sì tún ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe àwọn nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ tiyín.
21. Nítorí nǹkan ti ara wọn ni gbogbo àwọn yòókù ń wá, wọn kò wá nǹkan ti Jesu Kristi.
22. Ṣugbọn ẹ mọ bí Timoti ti wúlò tó, nítorí bí ọmọ tíí ṣe pẹlu baba rẹ̀ ni ó ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ pẹlu mi ninu iṣẹ́ ìyìn rere.
23. Nítorí náà, òun ni mo lérò pé n óo rán nígbà tí mo bá mọ bí ọ̀rọ̀ mi yóo ti já sí.
24. Ṣugbọn mo ní igbẹkẹle ninu Oluwa pé èmi fúnra mi yóo wá láìpẹ́.
25. Mo kà á sí pé ó di dandan pé kí n rán Epafiroditu pada si yín. Ó jẹ́ arakunrin mi, alábàáṣiṣẹ́ pẹlu mi, ati ọmọ-ogun pẹlu mi. Ó tún jẹ́ òjíṣẹ́ ati aṣojú yín tí ó ń mójútó àìní mi.
26. Nítorí ọkàn gbogbo yín ń fà á, ọkàn rẹ̀ kò sì balẹ̀ nítorí gbígbọ́ tí ẹ ti gbọ́ pé ó ṣàìsàn.
27. Òtítọ́ ni, ó ṣàìsàn, ó tilẹ̀ fẹ́rẹ̀ kú! Ṣugbọn Ọlọrun ṣàánú rẹ̀, kì í sìí ṣe òun nìkan ni, Ọlọrun ṣàánú èmi náà, kí n má baà ní ìbànújẹ́ kún ìbànújẹ́.