18. Kí ni àyọrísí gbogbo èyí? Lọ́nà kan tabi lọ́nà mìíràn, ìbáà ṣe pẹlu ẹ̀tàn ni, tabi pẹlu òtítọ́ inú, a sá ń waasu Kristi, èyí ni ó mú inú mi dùn. Inú mi yóo sì máa dùn ni,
19. nítorí mo mọ̀ pé àyọrísí rẹ̀ ni pé a óo dá mi sílẹ̀ nípa adura yín ati nípa àtìlẹ́yìn Ẹ̀mí Jesu Kristi,
20. gẹ́gẹ́ bí igbẹkẹle ati ìrètí mi pé n kò ní rí ohun ìtìjú kan. Ṣugbọn bí mo ti máa ń gbé Kristi ga ninu ara mi pẹlu ìgboyà nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ gan-an náà ni n óo tún máa gbé e ga nisinsinyii ìbáà jẹ́ pé mo wà láàyè tabi pé mo kú.
21. Nítorí pé Kristi ni mo wà láàyè fún ní tèmi, bí mo bá sì kú, èrè ni ó jẹ́.
22. Bí mo bá wà láàyè ninu ẹran-ara, iṣẹ́ tí ó lérè ni ó jẹ́ fún mi. N kò tilẹ̀ mọ èyí tí ǹ bá yàn.