Filemoni 1:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ǹ bá dá a dúró, kó máa wà lọ́dọ̀ mi, kí ó lè máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi dípò rẹ lákòókò tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n nítorí iṣẹ́ ìyìn rere.

14. Ṣugbọn n kò fẹ́ dá nǹkankan ṣe láìjẹ́ pé o lọ́wọ́ sí i, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé túlààsì ni oore tí mo fẹ́ kí o ṣe. Inú rẹ ni mo fẹ́ kí ó ti wá.

15. Bóyá ìdí nìyí tí ó fi sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀, kí o lè jèrè rẹ̀ ní gbogbo ìgbà;

16. kì í tún ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú mọ́, ṣugbọn ní ipò tí ó ga ju ti ẹrú lọ, bí àyànfẹ́ arakunrin, tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, ṣugbọn tí ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù mí lọ, gẹ́gẹ́ bí eniyan sí eniyan ati gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ.

17. Nítorí náà bí o bá kà mí sí ẹni tí a jọ gba nǹkankan náà gbọ́, kí o gbà á pada tọwọ́-tẹsẹ̀ bí ẹni pé èmi alára ni o gbà.

18. Ohunkohun tí ó bá ti ṣe sí ọ láìdára, tabi ohun tí ó bá jẹ ọ́, èmi ni kí o kà á sí lọ́rùn.

19. Èmi, Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ọ́ pé, n óo san án pada fún ọ. Kò tún nílò kí n sọ fún ọ pé ìwọ fúnrarẹ, o jẹ mí ní gbèsè ara rẹ.

20. Arakunrin mi, mo fẹ́ kí o yọ̀ǹda ọ̀rọ̀ yìí fún mi nítorí Oluwa. Fi ọkàn mi balẹ̀ ninu Kristi.

21. Pẹlu ìdánilójú pé o óo ṣe bí mo ti wí ni mo fi kọ ìwé yìí sí ọ; mo sì mọ̀ pé o óo tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.

22. Ó ku nǹkankan: Tọ́jú ààyè sílẹ̀ dè mí, nítorí mo ní ìrètí pé, nípa adura yín, Ọlọrun yóo jẹ́ kí wọ́n dá mi sílẹ̀ fun yín.

Filemoni 1