9. Ọjọ́ kẹtalelogun oṣù kẹta, tíí ṣe oṣù Sifani ni Modekai pe àwọn akọ̀wé ọba, wọ́n sì kọ òfin sílẹ̀ nípa àwọn Juu gẹ́gẹ́ bí Modekai ti sọ fún wọn. Wọ́n fi ranṣẹ sí àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn gomina, ati àwọn olórí àwọn agbègbè, láti India títí dé Etiopia, gbogbo wọn jẹ́ agbègbè mẹtadinlaadoje (127). Wọ́n kọ ọ́ sí agbègbè kọ̀ọ̀kan ati ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, wọ́n sì kọ sí àwọn Juu náà ní èdè wọn.
10. Wọ́n kọ ìwé náà ní orúkọ Ahasu-erusi ọba, wọ́n sì fi òrùka ọba tẹ̀ ẹ́ bí èdìdì. Wọ́n fi rán àwọn iranṣẹ tí wọn ń gun àwọn ẹṣin tí wọ́n lè sáré dáradára, àwọn ẹṣin tí wọn ń lò fún iṣẹ́ ọba, àwọn tí wọ́n ń bọ́ fún ìlò ọba.
11. Òfin náà fún àwọn Juu ní àṣẹ láti kó ara wọn jọ, láti gba ara wọn sílẹ̀, ati láti run orílẹ̀-èdè tabi ìgbèríko tí ó bá dojú ìjà kọ wọ́n, ati àwọn ọmọ wọn, ati àwọn obinrin wọn. Wọ́n lè run ọ̀tá wọn láì ku ẹnìkan, kí wọ́n sì gba gbogbo ìní wọn.
12. Àṣẹ yìí gbọdọ̀ múlẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Pasia, ní ọjọ́ tí wọ́n yàn láti pa gbogbo àwọn Juu, ní ọjọ́ kẹtala oṣù kejila, tíí ṣe oṣù Adari.