9. Habona, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, bá sọ fún ọba pé, “Igi kan, tí ó ga ní aadọta igbọnwọ (mita 22) wà ní ilé rẹ̀, tí ó ti rì mọ́lẹ̀ láti gbé Modekai kọ́ sí, Modekai tí ó gba ẹ̀mí rẹ là.”
10. Ọba bá ní kí wọ́n lọ gbé Hamani kọ́ sí orí rẹ̀. Wọ́n bá gbé Hamani kọ́ sí orí igi tí ó ti rì mọ́lẹ̀ fún Modekai, nígbà náà ni inú ọba tó rọ̀.