Hamani jáde pẹlu ayọ̀ ńlá, ati ìdùnnú. Ṣugbọn nígbà tí ó rí Modekai ní ẹnu ọ̀nà ààfin, tí kò tilẹ̀ mira rárá tabi kí ó wárìrì, inú bí i sí Modekai.