Ẹsita 2:20-23 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ṣugbọn Ẹsita kò sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ẹ̀yà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Modekai ti pàṣẹ fún un, nítorí ó gbọ́ràn sí Modekai lẹ́nu, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe nígbà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú rẹ̀.

21. Ní àkókò náà, nígbà tí Modekai jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin, meji ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà: Bigitana ati Tereṣi, ń bínú sí ọba, wọ́n sì ń dìtẹ̀ láti pa Ahasu-erusi ọba.

22. Ṣugbọn Modekai gbọ́ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sọ fún Ẹsita, ayaba, Ẹsita bá tètè lọ sọ fún ọba pé Modekai ni ó gbọ́ nípa ète náà tí ó sọ fún òun.

23. Nígbà tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n sì rí i pé òtítọ́ ni, wọ́n so àwọn ọlọ̀tẹ̀ mejeeji náà kọ́ sórí igi. Wọ́n sì kọ gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ ninu ìwé ìtàn ìjọba níwájú ọba.

Ẹsita 2