Ẹsita 2:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí ó yá, tí ibinu ọba rọlẹ̀, ó ranti ohun tí Faṣiti ṣe, ati àwọn àṣẹ tí òun pa nípa rẹ̀.

2. Àwọn iranṣẹ ọba tí wọ́n súnmọ́ ọn tímọ́tímọ́ bá sọ fún un pé,

3. “Jẹ́ kí á wá àwọn wundia tí wọ́n lẹ́wà fún ọba, kí á yan àwọn eniyan ní gbogbo ìgbèríko ìjọba rẹ̀ láti ṣa àwọn wundia tí wọ́n lẹ́wà wá sí ibi tí àwọn ayaba ń gbé ní ààfin, ní Susa, tíí ṣe olú ìlú, kí wọ́n wà lábẹ́ ìtọ́jú Hegai, ìwẹ̀fà ọba, tíí ṣe olùtọ́jú àwọn ayaba, kí á sì fún wọn ní àwọn ohun ìpara,

Ẹsita 2