Ẹsira 7:7-13 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ní ọdún keje ìjọba Atasasesi, díẹ̀ ninu àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti ìgbèkùn dé: àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn iranṣẹ ninu Tẹmpili,

8. wá sí Jerusalẹmu. Ní oṣù karun-un ọdún keje ìjọba Atasasesi ni Ẹsira dé sí Jerusalẹmu.

9. Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Babiloni ní ọjọ́ kinni oṣù kinni, ó sì dé Jerusalẹmu ní ọjọ́ kinni oṣù karun-un nítorí pé ó rí ojurere Ọlọrun.

10. Nítorí Ẹsira fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sí kíkọ́ òfin OLUWA, ati pípa á mọ́ ati kíkọ́ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

11. Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé tí ọba Atasasesi fún Ẹsira nìyí,

12. “Láti ọ̀dọ̀ Atasasesi ọba, sí Ẹsira, alufaa, tí ó tún jẹ́ akọ̀wé òfin Ọlọrun ọ̀run.

13. “Mo pàṣẹ jákèjádò ìjọba mi pé bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi bá fẹ́ bá ọ pada lọ sí Jerusalẹmu, kí ó máa bá ọ lọ;

Ẹsira 7