Ẹsira 7:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà, ní àkókò ìjọba Atasasesi, ọba Pasia, ọkunrin kan wà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹsira, ọmọ Seraaya, ọmọ Asaraya, ọmọ Hilikaya,

2. ọmọ Ṣalumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu,

3. ọmọ Amaraya, ọmọ Asaraya, ọmọ Meraiotu,

4. ọmọ Serahaya, ọmọ Usi, ọmọ Buki,

5. ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, olórí alufaa.

6. Láti Babiloni ni Ẹsira tí à ń wí yìí ti dé. Akọ̀wé ni, ó sì já fáfá ninu òfin Mose, tí OLUWA Ọlọrun Israẹli fún wọn. Ọba fún un ní gbogbo nǹkan tí ó bèèrè, nítorí pé ó rí ojurere OLUWA Ọlọrun rẹ̀.

7. Ní ọdún keje ìjọba Atasasesi, díẹ̀ ninu àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti ìgbèkùn dé: àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn iranṣẹ ninu Tẹmpili,

8. wá sí Jerusalẹmu. Ní oṣù karun-un ọdún keje ìjọba Atasasesi ni Ẹsira dé sí Jerusalẹmu.

Ẹsira 7