4. Kí ògiri jẹ́ ìlè igi kan lórí ìlè òkúta mẹta. Ninu ilé ìṣúra ààfin ọba ni kí wọ́n ti mú owó kí wọ́n fi san owó iṣẹ́ náà.
5. Gbogbo ohun èlò ìṣúra wúrà ati fadaka inú tẹmpili ní Jerusalẹmu, tí Nebukadinesari kó lọ sí Babiloni, ni kí wọ́n kó pada wá sí Jerusalẹmu, kí wọ́n sì fi wọ́n sí ààyè wọn ninu ilé Ọlọrun.”
6. Nígbà náà ni Dariusi ọba désì ìwé Tatenai pada, ó ní,“Sí Tatenai, gomina agbègbè òdìkejì odò, ati Ṣetari Bosenai ati àwọn gomina ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n wà ní agbègbè òdìkejì odò.
7. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀, ẹ má dí wọn lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí gomina Juda ati àwọn àgbààgbà Juu tún ilé Ọlọrun náà kọ́ síbi tí ó wà tẹ́lẹ̀.