Ẹsira 6:21-22 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Gbogbo àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ati àwọn tí wọ́n kọ ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà sílẹ̀ láti sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí wọn ń bá wọn gbé ní ilẹ̀ náà, tí wọ́n sì wá síbi ayẹyẹ náà pẹlu wọn, ni wọ́n jọ jẹ àsè náà.

22. Ọjọ́ meje ni wọ́n fi fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ Àjọ Àìwúkàrà, nítorí pé Ọlọrun ti fún wọn ní ayọ̀ nítorí inú ọba Asiria tí ó yọ́ sí wọn, tí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún ilé Ọlọrun Israẹli kọ́.

Ẹsira 6