1. Nígbà ti àwọn ọ̀tá Juda ati ti Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn dé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli,
2. wọ́n wá sọ́dọ̀ Serubabeli, ati sọ́dọ̀ àwọn baálé baálé, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á jọ kọ́ ọ nítorí ọ̀kan náà ni wá, Ọlọrun yín ni àwa náà ń sìn, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà ayé Esaradoni, ọba Asiria, tí ó mú wa wá síhìn-ín.”
3. Ṣugbọn Serubabeli, Jeṣua, ati àwọn baálé baálé tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli dá wọn lóhùn pé, “A kò fẹ́ kí ẹ bá wa lọ́wọ́ sí kíkọ́ ilé OLUWA Ọlọrun wa. Àwa nìkan ni a óo kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí Kirusi, ọba Pasia, ti pa á láṣẹ fún wa.”