Ẹkún Jeremaya 5:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa,Ṣe akiyesi ẹ̀sín wa.

2. Àwọn ilẹ̀ àjogúnbá ẹni ẹlẹ́ni,ilé wa sì ti di ti àwọn àjèjì.

3. A ti di aláìníbaba, ọmọ òrukànàwọn ìyá wa kò yàtọ̀ sí opó.

4. Owó ni a fi ń ra omi tí à ń mu,rírà ni a sì ń ra igi tí a fi ń dáná.

Ẹkún Jeremaya 5