Ẹkún Jeremaya 3:55-65 BIBELI MIMỌ (BM)

55. “Mo ké pe orúkọ rẹ, OLUWA, láti inú kòtò jíjìn.

56. O gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ̀ pé,‘Má ṣe di etí rẹ sí igbe tí mò ń ké fún ìrànlọ́wọ́.’

57. O súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi nígbà tí mo pè ọ́,o dá mi lóhùn pé, ‘Má bẹ̀rù.’

58. “OLUWA, o ti gba ìjà mi jà,o ti ra ẹ̀mí mi pada.

59. O ti rí nǹkan burúkú tí wọ́n ṣe sí mi,OLUWA, dá mi láre.

60. O ti rí gbogbo ìgbẹ̀san wọn,ati gbogbo ète wọn lórí mi.

61. “O ti gbọ́ bí wọn tí ń pẹ̀gàn mi, OLUWA,ati gbogbo ète wọn lórí mi.

62. Gbogbo ọ̀rọ̀ ati èrò àwọn ọ̀tá mi sí mi:ibi ni lojoojumọ.

63. Kíyèsí i, wọn ìbáà jókòó,wọn ìbáà dìde dúró,èmi ni wọ́n máa fi ń kọrin.

64. “O óo san ẹ̀san fún wọn, OLUWA,gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

65. Jẹ́ kí ojú inú wọn fọ́,kí ègún rẹ sì wà lórí wọn.

Ẹkún Jeremaya 3