51. Ìbànújẹ́ bá mi,nígbà tí mo rí ibi tí ó ṣẹlẹ̀sí àwọn ọmọbinrin ìlú mi.
52. “Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí ń dọdẹ mibí ìgbà tí eniyan ń dọdẹ ẹyẹ.
53. Wọ́n jù mí sinu ihò láàyè,wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ òkúta lù mí mọ́lẹ̀.
54. Omi bò mí mọ́lẹ̀,mo ní, ‘Mo ti gbé.’
55. “Mo ké pe orúkọ rẹ, OLUWA, láti inú kòtò jíjìn.
56. O gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ̀ pé,‘Má ṣe di etí rẹ sí igbe tí mò ń ké fún ìrànlọ́wọ́.’
57. O súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi nígbà tí mo pè ọ́,o dá mi lóhùn pé, ‘Má bẹ̀rù.’
58. “OLUWA, o ti gba ìjà mi jà,o ti ra ẹ̀mí mi pada.
59. O ti rí nǹkan burúkú tí wọ́n ṣe sí mi,OLUWA, dá mi láre.