12. Ó kẹ́ ọfà, ó fa ọrun rẹ̀,ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.
13. Ó mú gbogbo ọfàtí ó wà ninu apó rẹ̀ó ta wọ́n mọ́ mi lọ́kàn.
14. Mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́lọ́dọ̀ gbogbo eniyan,ẹni tí wọ́n fi ń kọrin tọ̀sán-tòru.
15. Ó mú kí ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́,ó fún mi ní iwọ mu ní àmuyó.
16. Ó fẹnu mi gbolẹ̀,títí yangí fi ká mi léyín;ó gún mi mọ́lẹ̀ ninu eruku
17. Ọkàn mi kò ní alaafia,mo ti gbàgbé ohun tí ń jẹ́ ayọ̀.
18. Nítorí náà, mo wí pé,“Ògo mi ti tán,ati gbogbo ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ OLUWA.”
19. Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi,ati ìrora ọkàn mi!
20. Mò ń ranti nígbà gbogbo,ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì.
21. Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan,mo sì ní ìrètí.
22. Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun,àánú rẹ̀ kò sì lópin;
23. ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀,òtítọ́ rẹ̀ pọ̀.
24. Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi,nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.”
25. OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é,tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀.
26. Ó dára kí eniyan dúró jẹ́ẹ́, de ìgbàlà OLUWA.
27. Ó dára kí eniyan foríti àjàgà ìtọ́sọ́nà ní ìgbà èwe.
28. Kí ó fi ọwọ́ lẹ́rán, kí ó dákẹ́, kí ó sì máa wòye,nítorí Ọlọrun ni ó gbé àjàgà náà kọ́ ọ lọ́rùn.
29. Kí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀,bóyá ìrètí lè tún wà fún un.
30. Kí ó kọ etí rẹ̀ sí ẹni tí ó fẹ́ gbá a létí,kí wọ́n sì fi àbùkù kàn án.