1. Èmi ni mo mọ bí eniyan tií rí ìpọ́njú,tí mo mọ bí Ọlọrun tií fi ibinu na eniyan ní pàṣán.
2. Ó lé mi wọ inú òkùnkùn biribiri.
3. Dájúdájú, ó ti dojú kọ mí,ó sì bá mi jà léraléra tọ̀sán-tòru.
4. Ó ti jẹ́ kí n rù kan egungun,ó sì ti fọ́ egungun mi.
5. Ó dótì mí,ó fi ìbànújẹ́ ati ìṣẹ́ yí mi káàkiri.
6. Ó fi mí sinu òkùnkùnbí òkú tí ó ti kú láti ọjọ́ pípẹ́.