Ẹkisodu 7:22-24 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ṣugbọn àwọn pidánpidán ilẹ̀ Ijipti lo ọgbọ́n idán wọn, àwọn náà ṣe bí Mose ati Aaroni ti ṣe, tí ó fi jẹ́ pé ọkàn Farao túbọ̀ yigbì sí i, kò sì gbọ́ ohun tí Mose ati Aaroni wí, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.

23. Dípò bẹ́ẹ̀, Farao yipada, ó lọ sí ilé, kò ka ọ̀rọ̀ náà sí rara.

24. Gbogbo àwọn ará Ijipti bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́lẹ̀ káàkiri yíká odò Naili, pé bóyá wọn á jẹ́ rí omi mímu nítorí pé wọn kò lè mu omi odò Naili mọ́.

Ẹkisodu 7