Ẹkisodu 40:36-38 BIBELI MIMỌ (BM)

36. Ninu gbogbo ìrìn àjò wọn, nígbà tí ìkùukùu yìí bá gbéra kúrò lórí àgọ́ náà, àwọn ọmọ Israẹli á gbéra, wọ́n á sì tẹ̀síwájú.

37. Ṣugbọn bí ìkùukùu yìí kò bá tíì gbéra, àwọn náà kò ní tíì tẹ̀síwájú títí tí yóo fi gbéra.

38. Nítorí pé ninu gbogbo ìrìn àjò wọn, ìkùukùu OLUWA wà lórí àgọ́ náà lọ́sàn-án, iná sì máa ń jó ninu rẹ̀ lóru ní ìṣojú gbogbo àwọn eniyan Israẹli.

Ẹkisodu 40