1. Ó fi igi akasia ṣe pẹpẹ ẹbọ sísun, bákan náà ni gígùn ati fífẹ̀ pẹpẹ náà rí, wọ́n jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹta.
2. Ó ṣe ìwo kọ̀ọ̀kan sí igun mẹrẹẹrin pẹpẹ náà, àṣepọ̀ mọ́ pẹpẹ ni ó ṣe àwọn ìwo náà, ó sì yọ́ idẹ bò wọ́n.