Ẹkisodu 37:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Besaleli fi igi akasia àpótí ẹ̀rí náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀, ó sì ga ní igbọnwọ kan ààbọ̀.

2. Ó yọ́ wúrà bò ó ninu ati lóde, ó sì tún fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀.

3. Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà, òrùka meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji.

4. Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n.

5. Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ inú àwọn òrùka tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà láti máa fi gbé e.

6. Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀.

7. Ó sì fi wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ṣe àwọn Kerubu meji, ó jó wọn mọ́ igun kinni keji ìtẹ́ àánú náà,

8. Kerubu kinni wà ní igun kinni, Kerubu keji sì wà ní igun keji.

9. Àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú náà; wọ́n kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìtẹ́ àánú.

10. Ó fi igi akasia kan tabili kan; gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀.

11. Ó yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, ó sì fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀.

Ẹkisodu 37