Ẹkisodu 30:34-36 BIBELI MIMỌ (BM)

34. OLUWA wí fún Mose pé, “Mú àwọn ohun ìkunra olóòórùn dídùn wọnyi: sitakite, ati onika, ati galibanumi ati ojúlówó turari olóòórùn dídùn, gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà.

35. Lọ̀ wọ́n pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn tí wọn ń ṣe turari, kí o fi iyọ̀ sí i; yóo sì jẹ́ mímọ́.

36. Bù ninu rẹ̀, kí o gún un lúbúlúbú. Lẹ́yìn náà, bù díẹ̀ ninu lúbúlúbú yìí, kí o fi siwaju àpótí ẹ̀rí ninu àgọ́ àjọ, níbi tí n óo ti bá ọ pàdé, yóo jẹ́ mímọ́ fún yín.

Ẹkisodu 30