Ẹkisodu 29:32-35 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo sì jẹ ẹran àgbò náà, ati burẹdi tí ó wà ninu agbọ̀n, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ.

33. Wọn yóo jẹ àwọn nǹkan tí wọ́n fi ṣe ètùtù láti yà wọ́n sọ́tọ̀ ati láti yà wọ́n sí mímọ́, eniyan tí kì í bá ṣe alufaa kò gbọdọ̀ jẹ ninu rẹ̀, nítorí pé mímọ́ ni wọ́n.

34. Bí ẹran ìyàsímímọ́ ati burẹdi náà bá kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, fi iná sun ìyókù, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ nítorí pé mímọ́ ni.

35. “Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe sí Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni kí o fi yà wọ́n sí mímọ́.

Ẹkisodu 29