7. Kí o ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, tí ọ̀pá yóo fi wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé e.
8. Fi pákó ṣe pẹpẹ náà, kí o sì jẹ́ kí ó jin kòtò, bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe é.
9. “Ṣe àgbàlá kan sinu àgọ́ náà. Aṣọ ọ̀gbọ̀ ni kí o fi ṣe aṣọ títa apá gúsù àgbàlá náà, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ,
10. àwọn òpó rẹ̀ yóo jẹ́ ogún, ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yóo sì jẹ́ ogún bákan náà, idẹ ni o óo fi ṣe wọ́n, ṣugbọn fadaka ni kí o fi ṣe àwọn ìkọ́ ati òpó rẹ̀.