Ẹkisodu 2:3-7 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Nígbà tí kò lè gbé e pamọ́ mọ́, ó fi koríko kan tí ó dàbí èèsún ṣe apẹ̀rẹ̀ kan, ó fi oje igi ati ọ̀dà ilẹ̀ rẹ́ ẹ, ó gbé ọmọ náà sinu rẹ̀, ó sì gbé apẹ̀rẹ̀ náà sí ààrin koríko lẹ́bàá odò.

4. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obinrin dúró ní òkèèrè, ó ń wo ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i.

5. Láìpẹ́, ọmọbinrin Farao lọ wẹ̀ ní odò náà, àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ sì ń rìn káàkiri etídò. Ó rí apẹ̀rẹ̀ náà láàrin koríko, ó bá rán iranṣẹbinrin rẹ̀ lọ gbé apẹ̀rẹ̀ náà.

6. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ọmọ kan ninu rẹ̀, ọmọ náà ń sọkún. Àánú ṣe é, ó wí pé, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Heberu nìyí.”

7. Ẹ̀gbọ́n ọmọ náà bá bi ọmọbinrin Farao pé, “Ṣé kí n lọ pe olùtọ́jú kan wá lára àwọn obinrin Heberu, kí ó máa bá ọ tọ́jú ọmọ yìí?”

Ẹkisodu 2