Ẹkisodu 16:17-36 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn mìíràn kó ju ohun tí ó yẹ kí wọ́n kó, àwọn mìíràn kò sì kó tó.

18. Ṣugbọn nígbà tí wọn fi ìwọ̀n Omeri wọ̀n ọ́n, àwọn tí wọ́n kó pupọ jù rí i pé, ohun tí wọ́n kó, kò lé nǹkankan; àwọn tí wọn kò sì kó pupọ rí i pé ohun tí wọ́n kó tó wọn; olukuluku kó ìwọ̀n tí ó lè jẹ.

19. Mose wí fún wọn pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣẹ́ ohunkohun kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.”

20. Ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí Mose lẹ́nu; àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, ohun tí wọ́n ṣẹ́kù ti bẹ̀rẹ̀ sí yọ ìdin, ó sì ń rùn, Mose bá bínú sí wọn.

21. Ní àràárọ̀ ni olukuluku máa ń kó ohun tí ó bá lè jẹ tán, nígbà tí oòrùn bá gòkè, gbogbo èyí tí ó bá wà nílẹ̀ yóo sì yọ́ dànù.

22. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹfa, wọ́n kó ìlọ́po meji, olukuluku kó ìwọ̀n Omeri meji meji. Nígbà tí àwọn àgbààgbà Israẹli lọ sọ fún Mose,

23. ó wí fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘Ọ̀la ni ọjọ́ ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀, ọjọ́ ìsinmi mímọ́ fún OLUWA. Ẹ dín ohun tí ẹ bá fẹ́ dín, kí ẹ sì se ohun tí ẹ bá fẹ́ sè, ohun tí ó bá ṣẹ́kù, ẹ fi pamọ́ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.’ ”

24. Wọ́n bá fi ìyókù pamọ́ títí di òwúrọ̀ gẹ́gẹ́ bí Mose ti sọ fún wọn; kò sì rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò yọ ìdin.

25. Mose wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ èyí lónìí, nítorí pé òní ni ọjọ́ ìsinmi OLUWA, ẹ kò ní rí kó rárá ní òní.

26. Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi máa rí oúnjẹ kó, ṣugbọn ní ọjọ́ keje tíí ṣe ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí níbẹ̀ rárá.”

27. Ní ọjọ́ keje, àwọn mìíràn ninu àwọn eniyan náà jáde láti lọ kó oúnjẹ, ṣugbọn wọn kò rí ohunkohun.

28. OLUWA bá wí fún Mose pé, “Yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo fi kọ̀ láti pa àṣẹ ati òfin mi mọ́.

29. Ẹ wò ó! OLUWA ti fún yín ní ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà ni ó fi jẹ́ pé, ní ọjọ́ kẹfa ó fún yín ní oúnjẹ fún ọjọ́ meji, kí olukuluku lè dúró sí ààyè rẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe jáde ní ilé rẹ̀ ní ọjọ́ keje.”

30. Àwọn eniyan náà bá sinmi ní ọjọ́ keje.

31. Àwọn eniyan Israẹli pe orúkọ oúnjẹ náà ní mana, ó rí rínbíntín-rínbíntín, ó dàbí èso igi korianda, ó funfun, ó sì dùn lẹ́nu bíi burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n fi oyin ṣe.

32. Mose wí fún wọn pé, “Àṣẹ tí OLUWA pa nìyí: ‘Ẹ fi ìwọ̀n omeri kan pamọ́ láti ìrandíran yín, kí àwọn ọmọ yín lè rí irú oúnjẹ tí mo fi bọ́ yín ninu aṣálẹ̀ nígbà tí mo ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá.’ ”

33. Mose bá sọ fún Aaroni pé, “Mú ìkòkò kan kí o fi ìwọ̀n omeri mana kan sinu rẹ̀, kí o gbé e kalẹ̀ níwájú OLUWA, kí ẹ pa á mọ́ láti ìrandíran yín.”

34. Aaroni bá gbé e kalẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA ti pa fún Mose.

35. Àwọn eniyan Israẹli jẹ mana náà fún ogoji ọdún, títí wọ́n fi dé ilẹ̀ tí wọ́n lè máa gbé, òun ni wọ́n jẹ títí tí wọ́n fi dé etí ilẹ̀ Kenaani.

36. Ìwọ̀n omeri kan jẹ́ ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa kan.

Ẹkisodu 16