Ẹkisodu 12:5-17 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ọ̀dọ́ aguntan tabi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà kò gbọdọ̀ lábàwọ́n, ó lè jẹ́ àgbò tabi òbúkọ ọlọ́dún kan.

6. Wọ́n óo so ẹran wọn mọ́lẹ̀ títí di ọjọ́ kẹrinla oṣù yìí. Nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli yóo pa ẹran wọn.

7. Wọn yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóo fi kun àtẹ́rígbà ati ara òpó ìlẹ̀kùn mejeeji ilé tí wọn yóo ti jẹ ẹran náà.

8. Alẹ́ ọjọ́ náà ni kí wọ́n sun ẹran náà, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati ewébẹ̀ tí ó korò bí ewúro.

9. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu ẹran yìí ní tútù, tabi bíbọ̀; sísun ni kí ẹ sun ún; ati orí rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ati àwọn nǹkan inú rẹ̀.

10. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó ṣẹ́kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, bí ohunkohun bá ṣẹ́kù, ẹ dáná sun ún.

11. Bí ẹ ó ṣe jẹ ẹ́ nìyí: ẹ di àmùrè yín mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín, ẹ wọ bàtà yín, ẹ mú ọ̀pá yín lọ́wọ́; ìkánjú ni kí ẹ fi jẹ ẹ́, nítorí pé oúnjẹ ìrékọjá fún OLUWA ni.

12. “Nítorí pé, ní òru ọjọ́ náà ni n óo la gbogbo ilẹ̀ Ijipti kọjá, n óo pa gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ náà, ati ti eniyan ati ti ẹranko, n óo sì jẹ gbogbo àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti níyà. Èmi ni OLUWA.

13. Ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá fi kun àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn gbogbo ilé yín ni yóo jẹ́ àmì láti fi gbogbo ibi tí ẹ bá wà hàn. Nígbà tí mo bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, n óo re yín kọjá; n kò ní fi àjàkálẹ̀ àrùn ba yín jà láti pa yín run nígbà tí mo bá ń jẹ àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti níyà.

14. Ọjọ́ ìrántí ni ọjọ́ yìí yóo jẹ́ fún yín, ní ọdọọdún ni ẹ óo sì máa ṣe àjọ̀dún rẹ̀ fún OLUWA; àwọn arọmọdọmọ yín yóo sì máa ṣe àjọ̀dún yìí bí ìlànà, gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí títí lae.

15. “Ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Láti ọjọ́ kinni ni kí ẹ ti mú gbogbo ìwúkàrà kúrò ninu ilé yín, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu láti ọjọ́ kinni títí di ọjọ́ keje, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́.

16. Ní ọjọ́ kinni ati ní ọjọ́ keje, ẹ óo péjọ pọ̀ láti jọ́sìn. Ní ọjọ́ mejeeje yìí, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ rárá, àfi oúnjẹ tí ẹ óo bá jẹ nìkan ni ẹ lè sè.

17. Ẹ óo máa ṣe àjọ̀dún ìrántí àjọ àìwúkàrà, nítorí ọjọ́ yìí ni ọjọ́ tí mo ko yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nítorí náà ẹ óo máa ṣe ìrántí ọjọ́ náà bí ìlànà ati ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín títí lae.

Ẹkisodu 12